Close

Àwon Erú Tí ó Féràn Sekésekè Wọn

Àwon Erú Tí ó Féràn Sekésekè Wọn

Abuja ni Gbade wa nigba ti won ranse pe wipe Baba re, Ifatunbi, ti j’Olorun nipe. Omije fere bo l’oju re, sugbon o se bi akinkanju niwaju onise ti won ran wa lati Ilu Fijapeta. O dupe lowo onise, o gbe ijoko timutimu fuun, o si ran okan lara omo awon alabagbe re ni oti elerindodo. O gbe ero amunawa re kekere sita lati tan. Nigba ti o taan tan, o wole pada, o si tan ero amohun maworan ti n be ninu yara igbafe ile re.

Nigba ti onise ti mu oti oyinbo ti o gbe si iwaju re tan, Gbade bere lowo re oun ti o sele ki Baba re, Ifatunbi to je Olorun nipe. Onise mi kanle, o sun ijoko re mo ti Gbade, o mi ori re, “Buroda Gbadegesin, sebi awon ijoba waa yi nooni.”

Gbadegesin run oju ko, “Bii ti bawo? La oro yii ye mi. Bi o tile je wipe gbogbo wa ni a mo wipe Ijoba ti n be ni orile ede yii ko se ise won bi ise, won ko si bikita fun emi awon ti o yan won si ipo, sugbon, bawo ni won se se okunfa iku ti o pa Baba mi?”

Onise tun mi kanle. “Sebi e mo wipe o ti to odun meta ti Baba agba ti feyinti lenu ise ijoba?” Gbade daa lohun wipe beeni. Onise tesiwaju. “Lati igba ti won ti feyinti ni won ti n paara ofiisi awon ijoba ti o n bojuto eto awon ti o ti feyinti. Sugbon, kaka ki won dawon lohun, nise ni won n gba won siwa, ti won n gba won seyin bii boolu afesegba. Oni, won a ni ki won ko leta si Alakoso Ofiisi ti o n ri si isuna owo. Ola, won a ni ki won ko leta si offisi Gomina ipinle. Beeni won se n ti won siwa seyin titi ti Baba fi subu dojudele ni ose ti o koja. Kaka ki awon ti o wa ni ofiisi yen tun gbe won, nse ni won n wo won niran titi ti won fi gbemi mi.”

Nigba ti onise se alaye tan, ati oun ati Gbade joko lai so ohunkohun fun bii iseju meedogun. Gbade dide, o koju si onise, o wipe, “Bi o tile je wipe awon eniyan wa a maa pa lowe wipe, “a kii ba onise rin”, sugbon, nibi ti oro gbe de bayii, emi ati iwo ni a o jo pada si ilu Fijapeta ni feere mojumo ola.”
Ni afemojumo owuro ojo keji ti o je satide, Gbade ati onise gbera lati lo si ibudoko ti won maa ti wo oko ti yoo gbe won lo si ipinle Eko, nibi ti won yoo ti wo oko ti yoo gbe won lo si Ilu Fijapeta. Nigba ti won de ibudoko, won ba eni merin ninu oko. Won ki won, won si darapo mo won. Leyin bii iseju meedogbon, oko ti kun. Awon oloko gba owo oko, leyin eyi, won gbera.

Bi won se n lo, arabinrin kan bere si ni fi ede fo. Leyin ti o ti fi ede fo fun bi iseju merin, o si bibeli re, o si bere si ni waasu. Leyin iwaasu re ti o gba iseju mewa, o gba adura fun gbogbo awon ti o wa ninu oko. Leyin eyi, o gbe apo kekere kan jade ni abe aga ijoko, o ni ki won ba oun gbee yika, wipe ki awon eniyan se itoore aanu lati fi mu ise ihinrere tesiwaju. Gbade rerin muse. Nigba ti arabinrin yen ti bere iwaasu ati ifedefo re ni Gbade ti mo ibi ti o n mu oro lo. Olukaluku lo n wa ona atije atimu.

Boya pelu ona ti o mo ni o abi ona eru, gbogbo eniyan ni o fe ni owo. Awon olori orile ede naa ko fi apeere rere mule fun awon ti won n dari. Lati odun 1960 ti orile ede Naijiria ti gba ominira lowo awon oyinbo ti o fi tipatipa daari won, awon ti o gba ijoba lowo awon oyinbo naa ko gbiyanju lati tun ilu se, abi lati pese ise fun awon eniyan won. Gbogbo owo ti o wa ninu apo ni won n ji ko lo si oke okun. Sebi ti ori ba ti baje, o di dandan ki awon eya ara toku yo idin. Ero yii ni Gbade n ro ti orun fi muu lo.

Nigbati o maa ji, o n gbo ariwo. Nigba ti o la ojuu re, ti o wo oun ti o n sele ni ita, o rii wipe awako won ni awon olopa da duro. Odomokunrin naa n fi ogorun naira be awon olopa, sugbon won n fi aake kori wipe afi dandan ki awon ki o gba igba naira ki awon to gba ki oko won lo. Leyin ti won fa oro naa siwaju seyin, okan lara awon ti o wa ninu oko ti owo bo apo, o yo ogorun naira, o si fi kun iye ti o wa ni owo awako. Afi igba yii ni awon olopa gbe igi ti won gbe dina bii igara olosa ti won si gbe ibon won sile, ti won je ki oko won lo.

Bi won se kuro nibe, ni awon ti o wa ninu oko bere si ni bu awon olopa yen. Awon miran tile n se epe fun won. Gbade mi ori re, o ba da awon ero inu oko toku lohun, “O da, e duro na. Kilode ti e ko fi so gbogbo eleyi niwaju awon olopa yen?”

Enikan dahun, o wipe, “Ta lo fe ku? Se ki won wa yin ibon fun mi ni? Awon omoo mi si kere. Iyawo mi paapa ko setan ati di opo osan gangan?”

Awon ero oko toku rerin, won si wipe “beeni o”.

“Sugbon, sebi ijoba wa naa lo wipe gbigba riba loju popona ko tona?” Gbade tun da won lohun.

Okan lara awon ero ti o joko si egbe awako ni iwaju ko oju seyin, o fuun lesi, “Oga oloyinbo. Sebi awon ijoba ti o n se oofin naa ni o n tapa si ofin naa. Awon ijoba ti o se ofin ma jale naa ni o n ji gbogbo owo ara ilu fun ilo ara won nikan. Awon ijoba ti o ni riba gbigba ko dara naa ni won n gba riba lorii gbogbo ise ti won ba gbe fun awon ile ise alagbase. Nigba ti awon oloori ko fi apere rere han, o di dandan ki awon ara ilu yoku fi owo gba ofin si egbe kan.”

Gbade mi kanle, “Sugbon se bi gbogbo re se maa tesiwaju leleyi? Ti a oo ma jiya, ti a oo si ma wo wan niran? Se bi won a se maa ko gbogbo owo iluu wa lo si oke okun niyen ti a o si maa se rankadede fun won?”

Baba agba kan ti o joko si eyin Gbade dahun, “Gbogbo ohun ti n sele ko kuku dun mo enikeni ti o feran ilosiwaju orile ede yii ninu, sugbon, emi ni sise? Sebi won ni, ti a ba ni ki a saami ese, ta lo le duro? Ni gbogbo awon egbe oselu ti o wa ni orile ede yi, tani o mo? Nje o le fi enikeni han mi ti owo re mo ninu ise owo ilu mokumoku? Ewo wa ni sise nigba ti o je wipe ti a ba yan egbe oselu A si ipo, ko le tun ilu se. Ti a ba yan egbe oselu B, si ipo, yoo baa je si ni. Ani ti a ba tun yan egbe oselu D si ipo, nigba ti won ba se ijoba tan, ilu Naijiria yoo buru jai ju ti tele lo ni. Ewo ni sise? Afi ki eledumare o gba wa lowo awon eniyan yi.”

Gbade rerin muse. “Baba Agba, eledumare ko ni ounkohuun se pelu oro ti o wa nile yi o. O da mi loju wipe ati igba ti eyin ti wa ni omode ni awon ara orile ede Naijiria ti n fi gbogbo isoro ati ona abayo kuro ninu isoro awon adari buburu sile fun olorun. Sugbon, e wo gbogbo re. E ko kii n se omode mo. E ti dagba. Sibesibe, e si tun fe ki a fi gbogbo re sile fun olorun. Sebi eyin agba naa le maa n so wipe, o ye ka jawo ninu apon ti ko yo, ki a da omi ila kana. Apon fifi gbogbo re sile fun eledumare lati wa idahun si isoroo orile ede wa ko yo mo, e je ka jawo ninu re ki a gbe omi ila ona miran kale. Apon lilo dibo ni odun merin merin lai ni ilosiwaju ko yo mo. E ja ki a jawo ninu re, ki a gbe omi ila ona miran kana.”

“Olorun ko ni sokale lati wa fun wa ni ominira o. Olorun ti fun wa ni opolo, o ti fun wa ni owo ati ese. O ti fun wa ni enu. O ti fun wa ni laakaye lati mo oun ti o dara yato si eyi ti o ku die kaato. Ti a ba si tesiwaju ninu igbekun, ko si eyi ti o kan olorun nibe o. Ti a ba tesiwaju lati maa je iya lai soro, ko kan eledumare o. Awon Yoruba bo, won ni, “Enu eni la fi n ko meje,” ati wipe, “Ma fi oko mi dana, ojo kan ni a n koo.” Ti a ko ba fariga, ki a je ki o ye awon adarii wa wipe, O to ge, won a tesiwaju lati maa se owo wa mokumoku, awon omo won naa a si tesiwaju pelu ilana yii lori awon omoo wa.”
Nigba ti awako ti o gbe won de ilu Fijapeta duro niwaju ile awon Gbade, awon omode kan sare wa baa gbe eru re. Iyaa re paapa sare jade, o di moo tipetipe. Pelu omije ni ojuu re, o wi fun Gbade wipe, “Gbadegesin, sebi o rii bi Baba re se lo gija ti o si fi emi nikan sile?”

“Maami, e je ki a wo inu ile. Ko kuku wun Baami naa lati lo lai dagbere. Sugbon ti olojo ba de, ta ni o lagbara to lati di idaa re mu?”

Nigba ti won wole, awon omo ti o baa gberu wole fi ogbon teseduro die; won n reti oun ti o ba won mu bo. O mu owo si inu eru re, o yo awon ohun mudunmudun, o si koo fun awon omo naa. Won dupe, won si sare lo ba awon elegbe won.

“Gege bi ilana awa musulumi, a ti gbin Baba re, Ifatunbi sinu ile.” Mama Gbade ni o bere oro. “Inuu mi ko dun wipe o ko si nibe, sugbon mo mo wipe ise ni ko je. Ati wipe, oke ibi ni ko je ki a ri oke ti ohun.”

Gbade mi kanle. “Eeen, Maami. Nigba ti mo n bo, ona yen ti baje patapata. Mo lero wipe Gomina ti o wa nibe se ileri wipe oun yoo tun ona yen se ni?”

Mama Gbade pose, “Sebi ti awon adarii wa ba ti n wa nkan ni won a maa dobale kiri, ti won yoo ma se oju aanu. Ti won ba ti yo tan, won a di oga ara won. Won a wa gbagbe gbogbo ileri ti won ti se fun ara ilu.”

“Sebi idibo ati yan awon asoju ijoba ibile ti de tan? Ti a ko ba tile ni asaaju rere gege bi olori patapata. Ti a ko ba tile ni gomina rere, sugbon ti a ba le yan olori rere ni ayikaa wa yi, awa na a le ri ilosiwaju die ti aa le fi erin si enu awon eniyan wa.”
Nigba ti ojo idibo lati yan awon asoju ijoba ibile ku ose kan, awon oniselu mewa ti o fe jo figagbaga ti n be ilu Fijapeta wo lati se ileri ati lati bebe fun iboo won. Gbade da meji ninu won mo. Okan ninu won ti o je omo egbe oselu Ominira fun Naijiria (OFN), Ogbeni Badaru Adeleke ni Gbade ti gbo iroyin re ni Abuja. O se omo ise fun okan lara awon asofin ni Abuja.

Sugbon agabara ti o n lo, o ju ti oga asofin funrara re. Ti awon eniyan ba wa si ofiisi oga re, ti won ko ba tii fun ni owo eyin, ko ni je ki won ri ogaa re. Ti eniyan ba fe ko leta sile fun ogaa re, ti ko ba ti mu owo sile, leta naa ko ni de odo oga. O wa ya Gbade lenu wipe iru eniyan bee le wa maa bebe fun ibo, ki o si maa se ileri ni orisirisi.

Eni keji ti Gbade mo lara awon ti o fe figagbaga ni Ogbeni Riliwanu Lasisi. Bi o tile je wipe won a maa ni wipe oselu kii se oun ti o ye ki omoluabi maa ti oju bo, ati wipe awon janduku ati oniwaburuku eniyan ni o n se oselu, sugbon Ogbeni Lasisi yato.

Ilu Ibadan ni Gbade ti koko pade re nigba ti Gbade n se odun kan osinlu re ni Ibadan. Ogbeni Lasisi a maa pe gbogbo won joko, a si maa ba won soro. Agbejoro ni. O korira ibaje, o si fi oofin n ba awon eni ibaje ja. Opo igba ni o maa n gba ejo awon alaini, ti a si bawon gba eto won lowo awon ti o fe fi du won lai gba iyekiye ni owo won. Ko si eni naa ti o ni ohunkohun so nipa Ogbeni Lasisi bi ko se ohun rere.

Nigba ti ojo idibo ku ojo kan, Gbade pe awon ara adugbo re joko, o n ba won soro. “Eyin araa mi, idibo di ola o. Ibo ni a fe dojuko?”

Okan lara awon odo ti o wa ni iduro dahun, “Ogbeni Badaru ni a ma tele o?”

Gbade bere wipe ki lo de.

“Ogbeni Lasisi yen jo eni ti o le se ise yen. A tile ti gbo okiki re kaakiri wipe eniyan rere ni, sugbon ko lowo lowo. Se enu didun ni awa fe je ni? Ogbeni Badaru ni tire ti fi ile poti, o ti fona roka. Se ni ti iresi ni, abi ti ewa. Se ti apo gaari mewa ti o ni ki won pin yika ni ki a so, abi ti ero ti won fi n ge irun ati masiini iranso ti o ko wo ilu? Ko si ani ani, Ogbeni Badaru ni a maa tele o.”

Gbade tun dahun, “Sugbon se e ro pe eleyi ba oju mu? O da naa, leyin ti e ba gba iresi ati ewa, ti e gba gaari, se gbogbo eleyii ko ni tan laarin ose kan tabi meji? Kinni e fewa maa se fun gbogbo odun merin ti won maa lo ni ori ipo? Ekinni, e ko ni ni enu oro, nitoripe, e ti gba ebun lati dibo. Ekeji, ilosiwaju ko ni de ba iluu wa nitoriwipe a yan eni ti ko kun oju osunwon si ipo. E je ki a ronu daradara o. Odun merin le tun aye wa se, o si le baaje ju bi o ti wa lo o.”
Ni irole ojo idibo, nigba ti won ti ka esi idibo tan, awon eniyan joko si idi ero asoromagbesi ati amohunmaworan won, won n reti ki won se ifilo eni ti o jawe olubori. Nigba ti won maa daruko, oruko Ogbeni Badaru ni won da wipe o jawe olubori. Won fi Ogbeni Lasisi han nibi ti o ti n bowo lowo Ogbeni Badaru lati kii ku ori ire. Omije gbon Gbade, o mi orii re.

O gbo ariwo nita. Nigba ti o jade sita, o ri awon odo ti won n korin kaakiri adugbo wipe awon ti bori. O mi orii re. Ko tii ye won oun ti won ko si, sugbon, ki odun merin yen to pari, oju won a la. Pakute Badaru ti mu ewuju awon ara ilu, o ku eni ti yoo yo won.

Oni ko ni ati n rii awon eru ti won feran sekeseke. Nigba ti won ba ri eni ti o le yo won, won a fi owo roo seyin, won a si pe amunileru won wipe ki o wa so sekeseke awon daradara, wipe ko soo daradara to.

Gbade wo inu ile pada, o pe mama re. “Maami, o fere dabi wipe ti mo ba n pada si ilu Abuja ni ojo meta oni, a jo n lo ni.”

Enu ya mama re. “Hare! Emi lo de?”

“Maami, se eri, eniti awon eniyan wa dibo yan kii se eniyan rara. Eranko ninu awo eniyan ni. Oun ti yoo si fi oju awon eniyan yi ri ko ni derun rara. Nitori naa, e bere si ni pale eru yin mo, ki e si dagbere fun awon ore ati ojulumo yin. Ti o ba ti di ojo meta oni, a jo n lo si Abuja ni.”
Ni ojo ti won n pada lo si Ilu Abuja, oko ti o gbe won sese kuro ni ilu Fijapeta, o fi ori le ona eko nigba ti won ri ti awon olopa n na awako oko kan mo inu erofo. Awako won bere lowo awon awako yooku ti o n ba awako ti won n na bebe wipe ki lo sele. Won salaye wipe direba naa ko tete kuro ni oju ona nigba ti oko ti o n gbe Ogbeni Badaru koja n bo. Eyi lo mu ki awon olopaa re sokale, ti won si fe na awako naa pa.

Gbade mi ori, o wo oju iyaa re. O wipe, “Sebi mo so fuun yin.”
Iya mi ori, o mi kanle, “A fi ki eledumare o gba awon eniyan wa o.”

“Eledumare ko ni ounkohun lati se pelu oro yii. Won ni aye lati gba ara won, sugbon, awojumo ati wobia ni o ko ba won. Ohun ti oju won ba ri ninu igbekun ti won fi owo won gbe wole, aa ma ro lokan won wipe, afowofa won ni.”

scroll to top