Itan Lati Owo Onkowe Minage Gloria Nwaniga
Itumo Si Ede Yoruba Lati Owo Onkowe James Ogunjimi
***
Maami fariya ni ojo ti Baami ti aburo mi, Boyi si Matwa Kei, ti n se olori awon ajijagbara wipe: “Fi owo modi omo mi titi di igba ti n oo fi ri owo ori yin san ti n oo si gba omoo mi pada.”
Leyin ti baami sun nkan si eyin ilekun ti awon ajijagbara poora si inu okunkun, maami dide gija bii wipe ijalo bo ara won. Won fa iborun won yo, won figbe bo enu. Won so fun baami wipe won ni ode ori ti won ba lero wipe Boyi yoo pada wale. Nje eti won di ni? Nje won o gbo iroyin omo awon aladugbo wa ti o darapo mo awon ajijagbara SALADEF? Nje won ro wipe omo dabi eni ibusun ti eniyan yoo ka pepe ti yoo si da pada fun oni nkan leyin ti o ba loo tan, tabi aso ti eniyan le ya lowo awon aladugbo?
Baami kan joko sibe, won n gbiyanju lati ma binu. Won pa ete won po, ila si fa si iwaju orii won. Ni ohun kelekele, won bi maami leere ohun ti won fe ki awon se. Nje maami ko mo wipe awon ajijagbaraa yi a ma be ori gbogbo ebi ti ko ba fun won lowo? Nje maami ko gbo iroyin bi won se gbe ori tutu bii ife ti won si fi ko si ori igi, tabi bi won tile se je bii ti Idi Amin? Nje maami setan lati je irora ti o wa pelu bibe eti won lati fun awon iidin je?
Nigba ti baami ma pari oro, ara maami ti su, oju won si ko fere, bii oju eni ti ko mo ohun ti o n so.
Mo duro si egbe ilekun ni ile idana, inuu mi n po bi wipe enikan n gba imu fa ifun mi yo.
A mo wipe won maa wa si ilee wa. A mo ni ojo ti Ogbeni Chesobar tii se ore baami ti o je oluko ni ile iwe alakobere Chepkurkur fi to wa leti wipe awon ajijagbara SALADEF ti ko oruko awon ti won n ran ijoba lowo lati pin ilee wa fun awon eya Ndorobo.
A mo wipe won yoo wa nitoriwipe baami ti ya awon asoju ijoba ti o maa n pin ile ni ada ati okun ni ojo naa. Nitori naa, nigba ti iroyin wa wipe won ti bere si ni doju ija ko awon asoju ijoba, maami bere si ni gbe apo iresi ati ewa lati fi ti eyin ilekun enu ona wa.
Ko ye mi boya iberu ni tabi iyemeji ni o mu emi ati Boyi rerin ni ojo naa nipa ero wipe awon ajijagbara SALADEF le doju ija ko awa ti a je omo eya kanna. Mo kan mo wipe a n se yeye nipa re ni ale ojo ti Matwa Kei kan ilekun ilee wa, ti o si so fun baami wipe: “Alagba, e fun wa ni egberun mewa owo ori ati ogbon oke owo odale loni bi kii se bee, a oo fi oju yin wina loni.”
Baami ko gbogbo oun ti won ni jade. Isuna owo won ti won toju si abe ibusun. Ero asoromagbesi won ti o se iyebiye. Ati, ibon ode won paapa. Nigbeyin, lati daabo bo ebi won, won se ileri lati ta maalu wa ti oruko re n je Mtambakaki ni ojo keji ki won si ko owo re fun awon ajijagbara SALADEF. Sugbon Matwa Kei mi orii re, o wipe: “Oo duro de ola ki o to ya awon asoju ijoba ni ada ati okun re. Emi o ni duro di ola lati gba owo yen. Muu wa nisinyi, bikosebe, gbogbo ebi re ti pari loni.”
Igba naa ni baami ti Boyi si Matwa Kei lati muu dani. Ojo naa ni baami mi ori won, ti won s iwi pelu ibanije pe: “Awon omokunrin wa, ti won mule lati daabo bo ile awon baba nla wa, won ti doju ko wa bii eranko ti ebi n pa ti o n je ifuun re.”
***
Aaro ojo keji ti Boyi lo, mo ji ba maami ti won joko si ori apoti ninu ile idana. Won ko wo oke. Nigba ti mo ki won kaaro, won ko dahun. Nigba ti mo po tii, ti mo si bere si ni da sinu nkan imomi, maami pariwo: “Oponu, o fe pari gbogbo tii, ki ebi le maa pa aburo re ti o ba de lati inu aginju. Se ku fuun.”
Won bere sini pa ariwo lori ounje ni awon ose ti o tele. Ni akoko, mo n salaye fun won wipe Boyi ko tii le de ni isinyi, ati wipe ti o ba de, n o dana miran fuun. Sugbon, won a kan dahun wipe: “Oponu, o fe pari gbogbo tii, ki ebi le maa pa aburo re ti o ba de lati inu aginju. Se ku fuun.”
Baami a ni: “Gbenu e soun, iwo obinrin yi. Waa fi enu re pa Boyi, elenu faya. Ko tii ku. O gbo mi?” Sugbon, bi baami ba se soro, maami a yi oju won si ogiri, pelu ohun kelekele, won yoo wipe awon n ri iran adaba funfun. Olorun awon omo Israeli n fi han awon wipe Boyi ti bo lowo awon SALADEF, o si ti n bo ni ile.
Leyin ti won ba da soro tan, idakeroro a bo inu ile bi alejo kerin.
***
Opolopo awon ara adugbo ni o be wa wo leyin ti Boyi lo. Won wa lati wa mi orii won ati lati so fun wa wipe awon duro peluu wa. Awon elomiran gun ejipa, won bere boya ohunkohun wa ti awon le se. Bee, awon elomiran wa lati so itan awon ti o sebe yen lo ti won si pada wa pelu iyanu. Nigba miran, ti were ti n se maami ba ti lole ti ara won si bale die, aa jo po tii, aa si joko ti awon ara adugbo lati soro nipa Boyi. Bi Boyi se pa igbeyawo awon mo nigba ti o fi idi re mule wipe awon ebora ko so ikun awon. Bi aawo duduu Boyi se lewa bii epo igi. Bi Boyi se n so ede geesi to dan lenu, ede geesi ti o tobi ju fun omo odun meedogun bii tire.
Mo maa n fi ilekun ile idana sile ni sisi ki n le gbo ohun awon ti o n soro. Leyin ojo die, awon alejo dinku, aa si duro odindi ojo kan lai ri alejo ti yoo wa mu tii ati lati ki wa pele.
Osupa tan yooo loke ni ale ojo ti Saulo elete janpa mu iroyin wa. Mo ri ori pipaa re lati ibi odi wa, mo si yara si ilekun.
“Ijoba ti pinu lati ti oju bo oro ti o wa nile yi nipa bibere ogun lati pa emi mo,” ni o so. “Awon igba jagunjagun ti orile ede Kenya ti wa lona ninu awon oko nla ti a kun ni awo ewe. Won n bo lati wa fin awon ajijagbara SALADEF jade. Ogun lori ile yii ti n pe ju, awaa yi na ni a si ti mi owo agbara ijoba titi.” O so owo agbara yii bi eni ti o n tu ito ireke, o si n mi owo re ninu afefe.
Ni afemojumo ojo keji, baami ati molebi wa, Kimutai, gbe iho kekere kan si eyin ile, won si gbe iti ogede kan ti won fi aso alawo ewe yi. “Iku, gba ara yi,” baami wi, “Gbaa, ki o si mase be idile mi wo mo.”
Mo duro si egbe koto, o n je iyalenu si mi wipe baami ti o je kristieni le gba iru awon nkan bayi gbo. Oorun ile tutu mu omije wa si oju mi. Mi o wo maami ti o joko sori ile tutu legbe mi ti won di ewu won mu mo igba aya. Won ko gba lati da iyepe si ori posi, won kan fi oju tele baami bi won se bu iyepe ti won si da si inu saare. Nigba ti baami fi agbelebu onigi si inuu saare, maami fohun pelu itara wipe awon ko ni lowo ninu sisin emi Boyi lo.
Oojo wa, o ro lopolopo.
Omi ojo gbe iho si ile, o si gbe awon eka igi ati ewe ati iyepe lo. Petepete pejo si egbe awon koto. Iji ja. O fa awon agbado yo nile bii ejo alawo ewe ti o ti ku. Ferese ati ilekun mi titi, ategun si gbe awon ewe soke ni ofurufu.
Iji yii tun gbe orule ile alamoo wa ati ti ile idana wa. Iji gbee ni ojo ti mo koko gboorun aginju Elgon. Oorun yen n gbooro bi ti eye nla ti n fo loke loke titi ti o fi da bi wipe o da iyee re bo awon ile ti o wa nile.
Ojo yi naa ni awon jagunjagun Kenya ti oko alawo ewe gbe de.
Gbogbo awa omode sa ere ninu ojo ti n fun lati duro si egbe titi lati wo awon jagunjagun yi. O n wun wa wipe ki awon okoo won daku si inu petepete ki a le ribi wo igbanu awon jagunjagun ti won fi awo oka se ti a si ti gbo wipe o maa n te ikun ti o tobi lo si ile. Awon okunrin darapo mo wa, a si jo to si egbe titi, a n ju owo si awon jagunjagun ti o de ike alawo ewe si ori.
Awon obinrin naa fi isebe ati igba omi won sile lati darapo mowa lati royin nipa turari olowo iyebiye ti awon jagunjagun n lo ti o n run bii elede ti won si fi n le awon iwin. Enikan bere si ni royin nipa bata awon jagunjagun ti won fi awo ooni se ti o je ki ese awon ologun ri bii ti omode jojolo.
Ni awon ojo ti o tele, maami ko jeun mo, won si bere si ni da soro. Ugali won yoo wa nibe lai si eni ti o fowokan titi ti esikanmi yoo fi bo ti n o si daa nu si ile awon adiye. Maa joko si enu ona ile idana, n o si maa ri bi won se n je enu wuyewuye ti won a si maa da soro wipe: “Nje n o tii je iya to? Eledua, so okun mo mi ninu.” Nigba miran, won a gbe oju soke, won a si ri mi, won a wipe: “Omobirin, nje o ranti? Nje o ranti bi eyin enu Boyi se gunrege?”
Leyin ose pupo ti mo fi se akiyesi maami, o su mi, mo si bere sini tele awon omode iyoku lo si ile baale ni Cheptap-burbur ni ibi ti awon jagunjagun de si. Ni ibe, a o maa gba odi yoju, a o si maa teti si itan awon jagunjagun ti a o si fi mu itan omiran jade fun ara wa. “Nje o mo jagunjagun dudu yen ti won n pe ni sajenti? Nje o le gbagbo wipe oun ni o pa Idi Amin ni orile ede Uganda? Mo gbo ti o n so fun awon iyoku re wipe Matwa Kei tun wa ni oogun ju Idi Amin lo, walahi, iwin ni okunrin yen.” N o maa ro, n o ri bi fila pupa ti Matwa Kei feran ju se n ta ota ibon danu ti ota ko fi le wo ara re tabi ba oju re ti o maa n gbona ni gbogbo igba.
Awon itan yii lo lati enu de enu bi obee gbona. Won mu mi ranti awon itan to Boyi maa n so fun mi nipa awon SALADEF: bi won se maa n gbe oogun babalawo mu ki ara won, gege bi iroyin Lwanda Magere, le di okuta ki ida awon otaa won ma le wole si won lara. Bi awon ajijagbara SALADEF se maa n sun sinu igbe maalu ki won to lo jagun ki won le bori awon otaa won. Bi o se je wipe ti awon ajijagbara SALADEF baa n rin ni ile, afefe pupa yoo ma fe loke bii esusu nitoriwipe orisa ile, Yeyiin, n lo pelu won.
Mo di awon itan yii mu sisin. Mo n gbadura wipe ki won je otito. Wipe ki Boyi lagbara ju awon jagunjagun.
Mo ranti osu kejila yen bii wipe ana ni. Awon agbe ko ro oko fun gbigbin agbado ni eekeji lodun nitoriwipe awon ajijagbara SALADEF ti ji awon nkan oko ati awon eran won. Kaka ki won sise, awon obinrin joko si ile, awon okunrin si pejo si abe awon igi bi won se n royin bi awon ajijagbara SALADEF se n be awon eniyan si wewe, ti won a si da won sinu odo, salanga, ati si inu konga.
“Won ti n lo si ojule de ojule lati maa fi tipatiwon mu awon omode ti omiran ninu won ko tii ju omo odun mewa lati darapo mo won. Ta ni o tile mo ohun ti won duro fun bayi mo? Won ti gbagbe wipe nse ni o ye ki won maa pa ile wa mo ki ijoba ma fi fun awon ole alapamasise Ndorobo. Nisinyi, won tile n be ori awa funrara wa danu. Kabontori, sebi eje pupa kanna ni ati awa Soy pelu awon Ndorobo ni? Mo tile gbo wipe awon ti o ba sese darapo mo won gbodo koko pada si ile lati lo pa molebi kan ti o sunmo won ki okan won le le lati pa awon miran.” Mo gbo ti ara adugbo wa, Koros n so fun baami lojo kan. “Ndugu Koros,” Baami dahun jeje, “O ye ki kinni yi ti dopin tipetipe, sugbon howu, bi idin ni oogun se maa n je okan awon eniyan.”
Ni ale ojo naa, mo lala ri wipe Boyi, ti ojuu re dudu bi ti oti elerindodo wa, o si be mi si wewe ki okan re le le lati pa awon eniyan miran. Nigba ti mo ji, mo fuye bi eni ti afefe n fe ninu re.
Irin ajo lo si Bungoma ati Uganda bere ni ojo ti omuu mi ti o le bi okuta bere si ni dun mi. Oree mi, Chemutai, ki ebi re to lo si Chwele, wipe eredi ti omuu mi fi tete tobi ni wipe kaka ki n maa sise bi omo obinrin tooto, nse ni maa dakun dele si abe igi ti n o si maa kawe.
Iberu bojo bo awon abule Kopsiro, Saromet, Chpeyuk, ati Chelebei. Iberu bo won nitori wipe ko si eni ti oro awon SALADEF ye mo. A soro nipa bi awon ajijagbara se n fi tipatipa mu awon omobirin lati lo dana fun won. Obirin kan tile wipe oun mo iya kan ti o je wipe nitori pe o ran gbogbo awon omokunrin re kuro ni abule, Matwa Kei dajo wipe ki won gba omobirin e ki o lo maa dana fun SALADEF.
Awon iroyin miran wa. Iroyin ibanuje. Itan bi odo Cheptap-burbur se pupa nitori eje awon ori awon eniyan ti o wa ninu re. Itan bi awon ajijagbara se n fi ipa ba awon molebi won lo po ti won o si bi awon omo ti o ri bi apo ikeru. Nigba ti awon itan yi de ile wa, maami wipe awon ko ni salo, awon ko ni fi Boyi sile, wipe ti baami ba fe lo, won le maa lo, ki won fi awon sile pelu omije awon. Iyen maami, ti won maa n gbe si eyin baami tele. Nitori ko si eni ti o n lo si ile iwe mo, maa ma joko si abe igi pelu ojuu mi ni pipade. N o maa fi oju tele awon ewe ti n jabo lori igi.
Iroyin wa pelu iji ti o n ja ni osu akoko. Iji ti o fe aso mi ti mo ka si aarin ese mi, ti o gbe aso mi soke si ibadi mi bi ibori. Boya ekun maami ni o fa isele laburu yi. O tile le je wipe tori baami faake kori, won ko soro nipa Boyi ni o je ki awon alale ile wa gbagbe lati daabo bo Boyi.
Ojo n ro, nitori naa, mo duro si oju ferese ile idana wa, mo n wo bi omi ojo se n jabo bi eyo iresi nigba ti mo ri Chesaina. Ore baami ni, o n se ise asode ni ile ise kan ni oja Chwele ti o wa ni ona jijin. Eyii ni o je ki o je iyalenu nigba ti mo ri won. Won joko si ori aga ijoko, won si n so fun maami ati baami wipe awon gbo iroyin lenu oloja kan ni Bukusu ti o gbo iroyin lenu osise ijoba nla kan wipe Boyi ti di eni a n wa. “Oun ni igba keji Matwa Kei. Howu, mama Boyi, ogun yi ti mu iye omo re lo.” Mo sa pamo si eyin ilekun ile idana, mo n fi egbe oju mi wo maami.
“Rara o!” Maami dahun pelu ohun arugbo won. “Ma ba mi so iru orokoro yen nipa omo mi. Chesaina, ti o ba nilo Omo lati fi fo enu idoti e, je ki a mo.” Omije bo oju won, won si ka owo mejeji sori. “Matwa Kei, kinni mo se fun e? So fun mi, Matwa Kei ki n le toro idariji.” Ohun won di, mo si fe wipe, Chesaina, pa enu re mo, sugbon ahon mi wuwo, o si ti le mo oke enu mi. Baami gbiyanju ati ro maami lekun. Won so fun won wipe omo rere ni Boyi, ati wipe, nje won ranti bi Boyi se maa n ka saamu tokantokan, pelu omije ni oju re? Maami o ye sunkun, nitori naa, Chesaina wo inu ojo, o si lo. Ni ojo naa, mo ri omije oju baami: o fa ila meji bi abo ajase.
Ni ale ojo yen, mo sun si ori ibusun Boyi fun igba akoko. Aso ibusun re alawo bulu ti won ya omo adiye ti o n jade lati inu ikarahun eyin si yi mo mi lara. O n run oorun re, ti erin re ti o dabi ebun ti a sese yo ninu pali, bi mudunmudun ti a sese tu ninu ewe re se maa n jade lati inu apo re bi wipe o n dara. Mo ranti bi o se maa n toju awon ohun ti baami ko fi aye gba bii awon nkan mudunmudun, si abe tabili. Mo te omuu mi ti o le bi okuta ti o n dun mi mo ori ibusun bii wipe ki irora ti Boyi n je ninu aginju di temi. Mo n fi oju inu woo, bi o se n wo bi mo se n so itan awon jagunjagun yen fun, paapaa, sajenti, iroyin eni ti mo mo wipe Boyi yoo feran lati gbo. Mo n fi oju inu wo bi a se n se bii jagunjagun bi a se maa n se nigba ti a wa ni omode, ti yoo wo aso ile iwe re ati emi ti mo wo ewu pelebe ti mo si n sapamo bi o se n pariwo: “Pa jagunjagun mo”. Maami ri wa ni ojo kan ti a n se ere yi, won si ba wa wi wipe a n fa ijamba si ara wa ati wipe a n pe iku loruko.
Mo mo wipe nkan buruku n bo ni ojo ti ara san ti monamona si fa igi eya Nandi ti o wa ni iwaju ile wa ya. Mo mo wipe nkan buruku n bo bi o tile je wipe maami bo sita ninu iyara won, won wipe monamona ti fa ibi ti o fe wa si idile wa ya pelu igi eya Nandi, ina si ti joo. Leyin eyi, won joko si egbee mi, a si jo n fi eti sile si bi awon eka igi se n faya si ori orule wa ti won si n mi ile titi. Leyin asale ojo yen, igi iwaju ile wa ko ruwe beeni ko so eso.
Ni owuro ojo keji, Simoni sare wo inu gbagede wa pelu iwe iroyin ti akole re so wipe Awon Jagunjagun Orile Ede Kenya Pa Awon Olori Awon Ajijagbara SALADEF. Inuu mi di po. Ayaa mi n ja bii wipe eniyan n fi ese lu mi ni aya bi mo se n sare bii olode ori ti mo si bere si ni gba ilekun iyara awon obii mi titi ti baami fi pariwo wipe: “Nje o ro wipe aarun iditi kolu wa ni oru oganjo ni?”
Mi o mira titi ti baami fi ka iroyin tan ti won si subu sile bi aso aloku. Mi o le oju nigba ti erin maami gba gbogbo ile kan. Mi o sunkun bi o se je wipe leyin wakati die, awon aladugbo wa bere si ni wole to wa ti won si n wipe: “Iku buruku ni n pani ni rewerewe.”
Maami ko yi nile bi Simoni se n royin bi won se mu Boyi ninu aginju. Won o sunkun nigba ti o wipe won gbe Boyi sinu oko ofurufu, nigba ti oko ofurufu gun oke ti o n fo loke bi eye, sajenti tii sita lati inu oko ofurufu ‘lai si ohun ti o ma je ki o fo, howu’.
Maami ko si abara de okuu Boyi lati bere lowo re eredi ti o fi fun awon ni buredi ibanuje je nitori wipe ko si oku lati gba. Kaka bee, won yi oju si baami, won wo won pelu oju won ti o kore lowo. Pelu itara ninu ohun won, won wi fun baami wipe sajenti ijoba ju Boyi awon sile lati inu oko ofurufu lai si ohun ti o ma je ki o fo, howu.
Ohun won ko koro. Ko ni ibanuje. O kan saa wa nibe ni. O ha die bii igi gedu ti ina ti jo. Maami ko soro gba baami nigba ti won mu ero asoromagbesi won ati iwe iroyin won ti won si daa sinu salanga.
Maami ko so wipe “ti o ba fe lo, lo sugbon fi mi sile lati sun ekun mi” nigba ti mo fa owo won, ti mo si dari won lo si iyara Boyi. Won kan joko si ori aso ori ibusun alawo bulu ti won ya odomodiye ti o n jade lati inu ikaraun eyin si ti won si n pe oruko Boyi jeje bii wipe agolo ni awon alifabeti oruko re ti yoo be won lenu ti won ba pa ariwo oruko re.
Mo je ki omije jabo ni ojuu mi. Mo je ki omije jabo si ori aso ti mo wo ati si ori ewu ti mo wo le omuu mi. Mi o so ohun ti mom o fun maami. Mi o so fun won wipe mo ni imolara ni igba ti emi kuro lara Boyi. Wipe mo ni imolara re tori wipe ni akoko ti monamona ko lu igi iwaju ile wa ti o si faa ya, iji yen padanu agbara re, o si di afefe yepere.
Lati ka itan Onkowe Minage Gloria Mwaniga yii ni ede geesi ti o fi ko: http://munyori.org/fiction/boyi-by-gloria-mwaniga-odary-kenya/